Lọjó Kinni, Osù Kẹta (Ẹrẹnà) 2013, àwọn olùlo twitter tó gbọ Yoruba yóò sọọ láti àárọ dálẹ.
A bẹrẹ ètò yìí lódún tó kọjá láti fá Twitter lẹsẹ kí wọn ba le fi ọn ba le fi èdè Yorùbá sí ọkan lára àwọn èdè àgbáyé tí a ti lè lo gbàgede náà. A se aseyọrí díẹ nígbà tí Twitter dá wa lóhùn padà láti ẹnu òsìsẹ ògbifọ wọn kan tí ó sọ wípé wọn ti gbọ ohùn wa, sùgbọn yó se díẹ kí wọn tó fi ọn tó fi Yorùbá kún-un nítorí àwọn ètò díẹ tí wọn ní láti se kí ó tó le seése.
A tún ti bá wọn sọrọ lẹẹkan síi nígbà tí òsìsẹ Twitter miran @lenazun wá láti bèèrè irú èka Yorùbá tí a máa n lò láti se ògbifọ àti láti kọ ìwé ìjọba ní Yorùbá. (Ìdáhùn rẹ ni Yorùbá Àríwá-Ìwọ Oòrùn, tí a n sọ ní Òyó). Léyìn èyí, nkò gbọ ohun mìràn.
ỌJọ Sísọ Yorùbá Ní Twitter ní March 1, 2003* jẹ láti tẹsíwájú èyí tí a bẹrẹ lódún tó kọjá, sùgbọn nísìnyí láti fi ẹwà èdè abínibí wa hàn nínú ayé ẹrọ ayélujára tí a n gbé nísìnyí. Ó lè má sẹlẹ rárá wipe ọjọ kan yóò wà tí èdè tí gbogbo aráyé yóò máa sọ lórí ayélujárá yóò jẹ èdè abínibí nìkan, torípé àwọn tó n sọ wón kò pọ púpọ (Yoruba tíẹ sí ní ju ọgbọn million lọ), sùgbọn bí ọnà láti sọ èdè yìí bá ti se wà, bẹẹ náà ni a ó se ní àìmọye ojúlówó ọnà láti fi àsà àti ìse wa hàn fún gbogbo àgbáyé
Bí a se seé lésìí, àwọn hashtags láti lò lọdún yìí ni #tweetYoruba àti #twitterYoruba. Fún àwọn tí wón bá tún fẹ fa Twitter lẹsẹ wípé kí wọn jẹ kí á se ògbifọ gbàgede náà sí Yorùbá, kí wón sèdà tweeti wọn sí @twitter àti @translator.
________
*February 21 ni Ọjọ Tí a Yà Sọtọ Lágbàáyé Fún Sísọ Nípa Èdè Abínibí
________
Èyí ni atọka ètò náà. Jọwọ fi han gbogbo àwọn ènìyàn rẹ lórí èrọ ayélujára
________
Àwọn olùlo twitter tí ó bá kọ àwọn oun tó mọgbọn wá jùlọ ní ọjọ yìí yóò gba asọ “Mo Le Sọ Yorùbá” àti báàgì ìfàlọwọ láti ọwọ @SpeakAfricaApps tí ó n se ìgbọwọ ètò yìí, ati kirediti lati owo Think Oyo (@ThinkOyo). Ètò yìí tún wá pẹlú àjọsepọ àwọn wọnyìí náà: Molara Wood, ònkọwé (@MolaraWood), Alakowe Yorùbá (@AlakoweYoruba), The Yoruba Cultural Insittute (@yorubaculture), àti Kevin “Kayode” Barry (@KayodeOyinbo).
_____________
No Comments to Ojo Siso Yoruba Ni Twitter 2013 so far. (RSS Feeds for comments in this post)
No one has commented so far, be the first one to comment!